Lóri ètò ìdájọ́ l'ọ́sẹ̀ yi, a tan iná wo àhesọ ọ̀rọ̀ kan tí ó ní sisé èémí fún ìṣejú àáyá mẹwa jẹ́ ọ̀nà lati mọ̀ bóyá èèyàn ní ààrùn COVID-19.
Atókùn ètò, Adébáyọ̀ Ààrẹ, jẹ k'ó di mímọ̀ pé ìròyìn irọ́ òhún bẹ̀rẹ̀ sí níí tàn kálẹ̀ ní osù kejì ọdún 2020, nígbà tí ọ̀rọ̀ àhesọ kan bẹ̀rẹ̀ síníí lọ káàkiri lójú òpó ìbánidorẹ Facebook, WhatsApp, àti Ìkànnì abẹ́yẹfò twitter pé tí èèyàn bá le sé èémí fún ìsẹ́jú àáyá mẹ́wa ajẹ́'pé ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní ààrùn COVID-19 nìyẹn.
Ìtànkálẹ̀ ọ̀rọ̀ ọ̀hún ni ìwádi fi hàn pé lati orí àwòráń kan tí wón ní ó wá lati ọwọ́ onísègùn òyìnbó ọmọ ilẹ̀ japan kan lóti bẹ̀rẹ̀, tí ó sì jẹ́ títàn kálẹ̀ lati ọ̀dọ̀ akọ̀ròyìn ilé'ṣẹ móhùnmáwòrán fox news tí orúkọ rẹ̀ n jẹ́ Geraldo Rivera lórí ètò kan nílé iṣẹ́ náà.
A gba àlejò onísègùn òyìnbó kan tí onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa àjàkálẹ̀ ààrùn, tí ó sì túń jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé isẹ́ tí ó ń rí sí ọ̀rọ̀ ààrùn COVID-19 nipinlẹ̀ Ọ̀yọ̀, tí ó bá wa tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ níì lati jẹ́ k'á mọ àyẹ̀wò tí ó tọ̀nà lati mọ̀ bóyá èèyàn ní ààrùn COVID-19 lárá, nínú síṣe àyẹ̀wò tí àwọn elétò ìlera f'ọwọ́ sí.
Lẹ́yìn àwọn òótọ́ ọ̀rọ̀, àti ìdásí àwọn akọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó, àti àwọn àjọ t'on rí sí ètò ìlera, ẹ dara pọ̀ mọ́ wa lati mọ ìdájọ́ wa lórí àhesọ ọ̀rọ̀ irọ́ náà.
The Production Team for this week’s episode are:
Olakunle Mohammed – Project Manager and Researcher
Oluwatosin Ologun – Producer
Adebayo Aare – Presenter